Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Wọ́n máa ń sọ pé bí ògiri ò bá lanu, aláǹgbá kò lè ráyè wọbẹ̀. Lọ́nà kan náà, táwọn kan bá ń bá ara wọn díje nínú ìjọ, ìyẹn máa mú káwọn ará kẹ̀yìn síra wọn. Tí àwọn ará bá sì kẹ̀yìn síra wọn, kò ní sí àlàáfíà nínú ìjọ, ẹ̀mí Ọlọ́run ò sì ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí kò fi yẹ ká máa bá ara wa díje, àá sì tún rí bá a ṣe lè jẹ́ kí ìjọ wà níṣọ̀kan.