Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kí nǹkan tó lè máa lọ dáadáa nínú ìdílé, kálukú gbọ́dọ̀ mọ ojúṣe rẹ̀, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Bàbá tó jẹ́ olórí ìdílé gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ìdílé ẹ̀. Ó ṣe pàtàkì kí ìyá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ ẹ̀, káwọn ọmọ náà sì máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí nínú ìdílé Jèhófà. Jèhófà ní ohun kan lọ́kàn fún wa, tá a bá sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀, àá wà lára ìdílé ẹ̀ títí láé.