Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀWÒRÁN: Torí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún tọkọtaya yìí láti fìfẹ́ hàn sí ara wọn àti sáwọn ọmọ wọn. Tọkọtaya yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sìn ín. Àwọn òbí náà lo fídíò láti ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi pèsè ìràpadà fún wa nípasẹ̀ Jésù. Wọ́n tún kọ́ àwọn ọmọ wọn pé nínú Párádísè, a máa bójú tó ayé àtàwọn ẹranko títí láé.