Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ṣé o ti gbọ́ ọ rí kí ẹnì kan tó ti pẹ́ nínú ètò Jèhófà sọ pé, ‘Mi ò ronú pé ayé burúkú yìí ṣì máa wà títí di àsìkò yìí’? Gbogbo wa pátá là ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fòpin sí ayé burúkú yìí, pàápàá lásìkò tí nǹkan nira gan-an yìí. Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ mú sùúrù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká lè mú sùúrù de àsìkò Jèhófà. Àá tún wo apá méjì nígbèésí ayé wa tá a ti gbọ́dọ̀ mú sùúrù ká sì dúró de Jèhófà. Paríparí ẹ̀, àá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún táwọn tó ń dúró de Jèhófà máa rí.