Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀWÒRÁN:Ojú Ìwé: Àtikékeré ni arábìnrin kan ti máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tó wà lọ́mọdé, àwọn òbí ẹ̀ kọ́ ọ báá ṣe máa gbàdúrà. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó di aṣáájú-ọ̀nà, ó sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn òun. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọkọ ẹ̀ ṣàìsàn, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun láti fara dà á. Ní báyìí, ó ti di opó, síbẹ̀ ó ṣì máa ń gbàdúrà déédéé torí ó dá a lójú pé Jèhófà Baba òun máa dáhùn àdúrà òun bó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.