Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gbà bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé ayé kàn ṣàdédé wà ni pé kò sẹ́ni tó dá a. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yẹn lè mú ká máa ṣiyèméjì bóyá Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan? A ò ní ṣiyèméjì tá a bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti Bíbélì túbọ̀ lágbára. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.