Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó máa ń dùn wá gan-an tí èèyàn wa kan bá fi Jèhófà sílẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. A tún máa rí àwọn nǹkan pàtó táwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì jó rẹ̀yìn. Bákan náà, a tún máa jíròrò ohun táwọn tó wà nínú ìjọ lè ṣe láti tu ìdílé náà nínú, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.