Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè gba gbogbo àkókò àti okun tó yẹ ká lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ló sábà máa ń dojú kọ àwọn ìpinnu tó lè nípa lórí ìgbésí ayé wọn fún ìgbà pípẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí máa ran ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n ṣe ìpinnu tó tọ́, kí ìgbéyàwó yín lè láyọ̀, kí ìgbé ayé yín sì lóyin.