Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà tí Jésù sọ pé àwọn àgùntàn òun máa fetí sí ohùn òun, ohun tó ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa fetí sí ẹ̀kọ́ òun, wọ́n á sì máa fi ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé méjì lára ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ wa yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́, ká má ṣe máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tara àti ìkejì, ká má máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè lo àwọn ìmọ̀ràn yẹn nígbèésí ayé wa.