Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ni ọ̀rẹ́ wa tó dáa jù lọ. A mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń wù wá ká túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè mọ ẹnì kan. Bákan náà ló rí téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí gan-an lóde òní, báwo la ṣe lè wáyè ká lè sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run? Àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?