Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kì í rọrùn láti fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Àmọ́, tó bá pọn dandan ká ṣe bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè ṣe é lọ́nà tó máa ṣe ẹni náà láǹfààní tó sì máa tù ú lára? Àpilẹ̀kọ yìí máa dìídì ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fún àwọn ará nímọ̀ràn lọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn náà.