Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ló dá gbogbo nǹkan. Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tá a sì ń jẹ́ kí ìlànà ẹ̀ máa darí wa. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́jọ tá a máa ń ṣe láti jọ́sìn Jèhófà. A tún máa kọ́ nípa bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́jọ yìí àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀.