Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Inú wa dùn a sì ń jàǹfààní torí pé a láwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́rin tí kì í jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà rọrùn. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn yanjú. Yàtọ̀ síyẹn, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa ti àwọn alàgbà lẹ́yìn, ká máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ká sì máa ṣohun táá jẹ́ kíṣẹ́ wọn túbọ̀ rọrùn.