Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kò sí àní-àní pé Tímótì mọ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere dáadáa. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣì gbà á níyànjú pé kó máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tí Tímótì bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà á, á túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará. Bíi ti Tímótì, ṣé ó wu ìwọ náà pé kó o túbọ̀ sin Jèhófà kó o sì yọ̀ǹda ara ẹ láti ran àwọn ará lọ́wọ́? Ó dájú pé ó wù ẹ́. Torí náà, àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn náà?