Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, ó gbéyàwó, òun àtìyàwó ẹ̀ sì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó bímọ, ó kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa wàásù, wọ́n sì jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Ó ti wá dàgbà báyìí, síbẹ̀ ó ṣì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó ń fi lẹ́tà wàásù.