Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Oríṣiríṣi nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí! Ìdí sì ni pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìfihàn ń ṣẹ lónìí. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe kàn wá? Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti méjì tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Ìfihàn. A máa rí i pé tá a bá ń ṣe ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.