Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn gan-an. Torí náà, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò àtohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù táwọn òbí yẹn máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìlànà Bíbélì mẹ́rin tó máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.