Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Àmọ́ nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń dárí jì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká gbà pé tá a bá ṣẹ̀, tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí jì wá.