Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Torí pé Kristẹni ni wá, àwa náà fẹ́ máa dárí ji àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a lè dárí ẹ̀ ji àwọn èèyàn àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a gbọ́dọ̀ fi tó àwọn alàgbà létí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa dárí ji àwọn èèyàn àti ìbùkún tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.