Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìbẹ̀rù máa ń dáàbò bò wá nígbà míì torí kì í jẹ́ ká kó sínú ewu. Àmọ́ ìbẹ̀rù tún lè pa wá lára. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Sátánì lè mú ká máa bẹ̀rù, ká sì ṣe ohun tí ò dáa. Àmọ́ a ò ní jẹ́ kí Sátánì kó jìnnìjìnnì bá wa. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? A máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí pé, tó bá dá wa lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, a ò ní bẹ̀rù.