Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó dojú kọ àdánwò tó le gan-an, ẹni tó sábà máa ń wá sí wa lọ́kàn ni Jóòbù. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin olóòótọ́ yẹn? A kẹ́kọ̀ọ́ pé Sátánì ò lè fipá mú wa pé ká má sin Jèhófà mọ́. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí Jèhófà ṣe gba Jóòbù lọ́wọ́ àwọn àdánwò tó dojú kọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa gbà wá sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Táwọn nǹkan yìí bá dá wa lójú, á jẹ́ pé àwa náà wà lára àwọn tó “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà” nìyẹn.