Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àìmọye èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ló ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lásìkò wa yìí. Ṣé o wà lára wọn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé Jésù Kristi Olúwa wa lò ń bá ṣiṣẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé ẹ̀rí kan yẹ̀ wò tó fi hàn pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Tá a bá ronú lórí ohun tá a máa jíròrò, á jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé Jèhófà làá máa sìn nìṣó bí Kristi ṣe ń darí wa.