Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Inú wa dùn pé Jèhófà fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà sí òun. A fẹ́ kí àdúrà wa dà bíi tùràrí tó ní òórùn dídùn, tó sì ń múnú Jèhófà dùn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè bá Jèhófà sọ tá a bá ń gbàdúrà. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó yẹ ká fi sọ́kàn tí wọ́n bá fún wa láǹfààní pé ká wá gbàdúrà.