Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn táwọn ọ̀dọ́ bá ṣèrìbọmi. Àmọ́ lẹ́yìn táwọn ọ̀dọ́ yìí bá ti ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.