Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní ayọ̀ tòótọ́ torí ohun tó ń fúnni láyọ̀ tòótọ́ kọ́ ni wọ́n ń fayé wọn ṣe. Wọ́n ń lépa ìgbádùn, ọrọ̀, òkìkí àti bí wọ́n ṣe máa di alágbára. Àmọ́ nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ bí àwọn èèyàn ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́.