Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga, ìyẹn àwọn ìjọba ayé yìí. Àmọ́ àwọn ìjọba kan máa ń ta ko Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Torí náà, báwo la ṣe lè máa tẹrí ba fáwọn alákòóso ayé, ká sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run?