Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọgbọ́n tí Jèhófà máa ń fún wa ju ohunkóhun tí ayé yìí lè fún wa lọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe kan nínú ìwé Òwe tó dá lórí ọgbọ́n tòótọ́ tó ń ké jáde ní ojúde ìlú. Torí náà, a máa mọ bá a ṣe lè ní ọgbọ́n tòótọ́, ìdí táwọn kan fi kọ etí dídi sí ọgbọ́n tòótọ́ àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ní ọgbọ́n tòótọ́.