Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì kan máa ń bá ara wọn jà, àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí i. (1 Ọba 12:24) Ṣùgbọ́n nígbà míì, Jèhófà máa ń fọwọ́ sí irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ẹ̀yà kan ti kẹ̀yìn sí i tàbí nítorí pé wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì.—Oníd. 20:3-35; 2 Kíró. 13:3-18; 25:14-22; 28:1-8.