Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà ń gbà ran àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro, ká sì máa láyọ̀. A máa gbé ìwé Àìsáyà orí ọgbọ̀n (30) yẹ̀ wò, ká lè mọ nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà máa ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Bá a ṣe ń gbé orí Bíbélì yìí yẹ̀ wò, a máa rán wa létí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa báyìí àtèyí tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.