Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ṣé o máa ń ronú nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè? Ohun tó dáa lò ń ṣe yẹn. Ìdí ni pé bá a ṣe túbọ̀ ń ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, bẹ́ẹ̀ lá máa túbọ̀ yá wa lára láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láyé tuntun fáwọn èèyàn. Jésù ṣèlérí pé Párádísè ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí tí Jésù ṣe yẹn túbọ̀ lágbára.