Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ayé yìí máa darí wọn. Ó dájú pé ìmọ̀ràn yẹn wúlò fún àwa náà lónìí. Ó yẹ ká ṣọ́ra, kí àwọn èèyàn ayé má bàa kó ìwà wọn ràn wá. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá à ń ronú lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa ronú lọ́nà tó tọ́.