Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù, ìdí tó fi kú àti ìfẹ́ tóun àti Bàbá rẹ̀ fi hàn sí wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó fi hàn pé a mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ìràpadà àti ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, bá a ṣe lè jẹ́ onígboyà, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà.