Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi. Àmọ́ kí ló máa jẹ́ kí ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi? Ìfẹ́ ni. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ fún kí ni àti fún ta ni? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àá sì sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí tá a bá ṣèrìbọmi tá a sì di Kristẹni.