Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló máa ń rántí ìgbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, tí àwọn àti òbí wọn máa ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tí wọ́n sì ń gbádùn wọn. Wọ́n máa ń rántí bí àwọn òbí wọn ṣe fi àwọn nǹkan yẹn kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Tó o bá ní ọmọ, báwo lo ṣe lè fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run? A máa dáhùn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí.