Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó mú kí ìjì pa rọ́rọ́, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì jí òkú dìde. Inú wa máa ń dùn tá a bá ń kà nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Wọ́n kọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, kì í ṣe ká kàn máa kà wọ́n bí ẹni ka ìwé ìtàn. Torí náà, bá a ṣe ń gbé díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu náà yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, wọ́n á jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Jésù, wọ́n á sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tó yẹ ká ní.