Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká máa ń gba àwọn èèyàn lálejò gan-an, wọ́n sì kà á sí ojúṣe pàtàkì. Ẹni tó bá gba àwọn èèyàn lálejò máa ń se oúnjẹ tó pọ̀ gan-an débi pé àwọn àlejò máa jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù. Torí náà, tẹ́nì kan bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ lòun fẹ́ ṣe àwọn èèyàn lálejò, pàápàá tó bá jẹ́ níbi ìgbéyàwó, á filé pọntí, á sì fọ̀nà rokà.”