Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a A máa ń gba ara wa níyànjú tá a bá dáhùn nípàdé ìjọ. Àmọ́ ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan láti dáhùn nípàdé. Inú àwọn kan sì máa ń dùn láti dáhùn, torí náà wọ́n máa ń fẹ́ kí wọ́n pè wọ́n léraléra. Bóyá ẹ̀rù máa ń bà wá láti dáhùn tàbí ẹ̀rù kì í bà wá, báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń gba ti ara wa rò ká lè fún ara wa níṣìírí? Báwo la ṣe lè fi ìdáhùn wa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ró kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ rere? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí.