Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó máa ń wù wá pé ká gbàdúrà sí Jèhófà látọkànwá, bí ìgbà tá a bá kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ wa kan tímọ́tímọ́ tá a sì sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ráyè gbàdúrà. Ó tún máa ń ṣòro fún wa láti mọ ohun tó yẹ ká gbàdúrà nípa ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì méjì yìí.