Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà yan Gídíónì láti máa bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀, kó sì máa dáàbò bò wọ́n lásìkò tí nǹkan nira lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ni Gídíónì fi ṣe iṣẹ́ náà tọkàntọkàn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìṣòro ló bá pàdé nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tẹ́yin alàgbà lè kọ́ lára Gídíónì tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ tó dán yín wò.