b Ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n ara ẹni jọra. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, a ò ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, àá sì gbà pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ṣe bíi pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ. (Fílí. 2:3) Ká sòótọ́, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń nírẹ̀lẹ̀.