Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní 1 Tẹsalóníkà orí 5, a rí àwọn àpèjúwe àtàwọn àfiwé tó jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, kí ni “ọjọ́ Jèhófà,” báwo ló sì ṣe máa dé? Àwọn wo ni ò ní pa run? Àwọn wo ló máa pa run? Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yẹ̀ wò.