Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rù” nínú Bíbélì. Ohun tí ìjíròrò náà bá dá lé ló máa fi hàn bóyá ohun tó ń kó jìnnìjìnnì bá èèyàn ni wọ́n ń sọ, ó sì lè jẹ́ ọ̀wọ̀ tàbí ẹ̀rù ni wọ́n ń sọ nípa ẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù táá mú ká jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà Baba wa ọ̀run, ká sì nígboyà.