Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó yẹ káwa Kristẹni bẹ̀rù Ọlọ́run, ká má sì ṣe ohun tó máa múnú bí i. Ìbẹ̀rù yìí ò ní jẹ́ ká ṣèṣekúṣe, a ò sì ní máa wo ìwòkuwò títí kan fíìmù tàbí àwòrán ìṣekúṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin ìṣàpẹẹrẹ méjì tí ìwé Òwe orí 9 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, tó jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ láàárín ọgbọ́n àti ìwà òmùgọ̀. Ó dájú pé àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú orí yìí máa ṣe wá láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.