Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀. Irú ìpọ́njú ńlá yìí ò tíì wáyé rí, àmọ́ tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń múra sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìfaradà, ká jẹ́ aláàánú, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n láwọn ànímọ́ yìí, a tún máa rí bá a ṣe lè fara wé wọn àti báwọn ànímọ́ yẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá.