Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àtìgbà ayé Ádámù àti Éfà ni Sátánì ti jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn fúnra wọn ló yẹ kó máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́. Ohun tí Sátánì fẹ́ káwa náà máa rò nípa àwọn ìlànà Jèhófà àtohun tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe nìyẹn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè yẹra fún ìwà tinú mi ni màá ṣe tó kúnnú ayé tí Sátánì ń darí yìí, àá sì tún rí bá a ṣe lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo.