Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa ni kò dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 14:22, 23) Jèhófà sọ pé àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún àtàwọn tó dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ máa kú sí aginjù. (Nọ́ń. 14:29) Àmọ́, Jóṣúà, Kélẹ́bù àti ọ̀pọ̀ àwọn tí ò tó ọmọ ogún (20) ọdún pẹ̀lú ọ̀pọ̀ lára ẹ̀yà Léfì ò kú, wọ́n la Odò Jọ́dánì kọjá, wọ́n sì wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Diu. 1:24-40.