Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn míṣọ́nnárì kan ò kúrò lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Peter Vanderhaegen àti Len Davis ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n sì ti dàgbà tó láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Ẹlòmíì ni Arábìnrin Marian Tambunan tó fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Indonéṣíà. Torí àwọn ìdí yìí, ìjọba gbà kí àwọn mẹ́ta yìí dúró sí Indonéṣíà. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí sì fi ìtara wàásù, Jèhófà sì bù kún iṣẹ́ wọn gan-an ní gbogbo àsìkò tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa.