Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọdún 1999 la ṣe odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Indonesian. Ọdún méje gbáko ni àwọn atúmọ̀ èdè fi ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè parí iṣẹ́ lórí Bíbélì náà, láìka pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n gbé ìwé Insight on the Scriptures, jáde lédè Indonesian. Lẹ́yìn náà ni wọ́n tún ṣe Watchtower Library on CD-ROM, jáde lédè Indonesian. Ó dájú pé iṣẹ́ ńlá làwọn atúmọ̀ èdè náà ṣe!