Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
e Kí Parker tó ṣe ìtumọ̀ Bíbélì ẹ̀ jáde, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun tí wọ́n kọ lédè Hébérù lo orúkọ Ọlọ́run láwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Bákan náà lọ́dún 1795, Johann Jakob Stolz tẹ ìtumọ̀ Bíbélì kan jáde lédè German, orúkọ Ọlọ́run sì fara hàn ní ohun tó ju àádọ́rùn-ún (90) ìgbà lọ nínú ìwé Mátíù sí Júùdù.