Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ṣe aago tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock. Aago yìí ni wọ́n fi ń mọ bí ìparun ayé yìí ṣe sún mọ́ tó àti bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń fi ọwọ́ ara wa ṣe ṣe máa fa ìparun náà. Ohun kan ni pé àfiwé lásán ni aago yìí, ó kàn ń jẹ́ ká mọ àwọn ìṣòro tá a gbọ́dọ̀ yanjú káwa èèyàn má bàa fọwọ́ ara wa pa ayé yìí run.”—Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists.